Táíwò Adéyẹmí
Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Akápò ẹgbẹ́ òsèlú òní tèsíwájú APC nìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Fẹ́mi Kújẹbọ́lá lórí ètò kan “APC Reconciliation Half Hour” ní Diamond 88.5FM, Iléshà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun wípé Gómìnà Adémólá Adélékè fagilé ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ nìpínlè Ọ̀sun.
Àwọn ènìyàn tí wọ́n lé ní mílíọ́nù mẹ́ta ló tẹ́tísí ètò yìí nìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tí àwọn tí wọ́n lé ní mílíọ́nù mẹ́fà sì gbọ ní àwọn ìpínlẹ̀ tó sún mọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nìpínlè Ọ̀sun nínú oṣù karùn-ún ọdún 2006, lábé ìṣàkóso Gómìnà Ọlágúnsóyè Oyinlolá.
Gómìnà Rauf Arẹ́gbẹ́sọlá ló mú àtúnṣe débá ètò ọ̀hún lọ́dún 2012 pẹ̀lú àpèlé O’meal àti àwọn àtúnṣe míràn.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Ìwádìí tí a ṣe lórí ẹ̀rọ gúgù fihàn pé ijọba àpapọ̀ ṣe ìgbàsàkóso ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2016, ní gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì àti ìlú Abújá. Èyí wáyé kí Gómìnà Adélèké tó gorí ipò àṣẹ lọ́dún 2022.
DUBAWA kàn sí adarí tẹ́lẹ̀rí fún ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lábé ìjòba àpapọ̀ nìjọ́ba ìbílẹ̀ Oríadé, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọmolọlá Joseph. Ó ṣàlàyé pé ìjọ̀ba àpapọ̀ ti gbàsàkóso ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ láti ọdún 2016 lábé ìṣàkóso Ààrẹ Muhammadu Buhari ní gbogbo àwọn ìpínlẹ̀.
Ó tèsìwájú pé “Ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nìjọ́ba àpapọ̀ ti gbà lọ́wọ́ àwọn ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ làti ọdún 2016”.
A tún kàn sí agbẹnusọ fún Gómìnà Adélékè, Ọláwálé Rasheed lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó sàlàyé pé ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti kúrò lábé ìsàkóso ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ láti ọdún 2016, tí Gómìnà Adélékè kò sì dá dúró.
Rasheed tèsìwájú pé “Ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ kò sì lábé ìsàkóso ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun mó láti ọdún 2016, ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lábé ìsàkóso Gómìnà Adélèké kò sì fagilé ètò ọ̀hún. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ nìpínlè Ọ̀ṣun sì ń jẹ àǹfààní ètò ọ̀hún”.
Bákannáà, a tún kàn sí Arábìnrin Fúnmiláyọ̀ Atóyèbí, olùkọ́ nílé’wé alákọ́bèrẹ̀ Young Tajudeen “YDI” Àgbáńgúdú, Ẹdẹ, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó wípé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kílààsì àkọ́kọ́ sí kílààsì kẹta gba oúnjẹ ọ̀fẹ́.
Arábìnrin Atóyèbí sàlàyé pé “àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nísà tó parí nínú osù kẹta ọdún 2024 sì jẹ óúnjẹ ọ̀fẹ́, ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ sì tèsìwájú.”
Àkótán
Kò sí òtítọ́ nínú àhèsọ pé Gómìnà Adélékè ti fagilé ètò óúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé’wé alákọ́bèrẹ̀ nìpínlè Ọ̀ṣun. Òfégé tó le ṣini lọ́nà ni ọ̀rọ̀ náà.
The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to enrich the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.