Àhesọ pé ewé mọ̀ríńgà le wo àrùn ìtọ̀ ṣúgà, ẹ̀jẹ̀ ríru mú òtítọ́ díẹ̀ dání


By Táíwò Adéyẹmí.

Àwòrán ewé mọ̀ríńgà. Orísun Àwòrán: HerZindagi.

Àhèsọ: Wida’du Rosul Islamic Foundation pín fọ́nrán kan lójú òpó Facebook wípẹlú àhesọ pé ewé mọ̀ríńgà le wo àìsàn ìtọ̀ súgà àti ẹ̀jẹ̀ ríru.

Àbájáde: Ìwádìí ìmọ́ sáyẹ́nsì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn oníṣègùn òyìnbó fihán pé, lótìítọ́, ewé mọ̀ríńgà ní àwọn èròjà tó lè ṣe ìtọ́jú àìsàn ìtọ̀ súgà àti ẹ̀jẹ̀ ríru. Sùgbọ́n, kò tíì sí ìdánilójú pe ewé yìí lè wòó àrùn wọ̀nyí pátá pátá.

Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Aṣàmúlò ojú òpó Facebook, Wida’du Rosul Islamic Foundation wípé ewé mọ̀ríńgà le wo àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru. Nínu fọ́nrán kàn tí arákùnrin ọ̀hún pín láìpẹ́ yìí, o gba àwọn tó ní àìsàn ìtọ̀ súgà àti ẹ̀jẹ̀ ríru níyànjú láti ṣe ewé mọ̀ríngà lágbo, kí wọ́n sì máa gbée mu. Lẹyìn ọjọ́ méje, àwọn àìsàn wọ̀nyí yóò di ohun ìgbàgbé.

O wípé, “Fún àǹfààní ìwọ tó bèrè fún ìtọ̀jú àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, mú ewé mọ̀ríńgà, ó pọ̀ ní gbogbo àyíká, gbé ka ná bí àgbo. Muú làárọ̀ àti ásàlẹ́ fún ọjọ́ méje, lo ṣe àyẹ̀wò ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, àwọn àìsàn ọ̀hún yóò ti lọ”.

Aṣàmúlò ojú òpó Facebook,  Akínlàwọ́n Adémọ́lá sọ pé “òtítọ ni.”

Bákannáà ni aṣàmúlò mìíràn “Healthy and Drug Free” dá si  pé àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru le sàn nípa lílo mọ̀ríngà. 

“Àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru le ṣàn,” ló kọ kalẹ̀.

Àwọn aṣàmúlò Facebook tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta ló ti wo fọ́nrán ọ̀hún, tí ẹgbẹ̀ta sì tí pin lọ́jọ́ kẹríndínlọ́gún, oṣù kẹfà ọdún, 2024. DUBAWA ṣ’àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà nítorí bó ṣe ràn tó.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Àìsàn ìtọ̀ súgà ma ń wáyé nígbà tí súgà (glucose) bá pọ̀jù lára, tí òroǹró kò sì leè lọ isulínì dáadáa. Kò sí ọjọ́ orí tí àìsàn ìtọ̀ súgà kò le ṣe àmọ́, ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn ènìyàn tí wọn tó ọmọ ọdún márùndínlọ́gọ́ta. Àwọn èèyàn tí wón lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin ló ń dágbére fáyé lọ́dún kan látàrí àìsàn ìtọ̀ súgà.

Ẹ̀jẹ̀ ríru le fa ìpèníjà àìsàn ọkàn, ìpèníjà àìsàn ọpọlọ, ìpèníjà àìsàn kíndìnrín àti àwọn àìsàn míràn. Àìsàn ọ̀hún wọ́pọ̀ láàrín àwọn ènìyàn tọ́’jọ́ orí wọn jẹ́ ọdún márùndínlógọ́ta sí ọdún márùndínláàdọ́rin. Àwọn ènìyàn tí wọ́n tó mílíọ̀nù méje àti àbọ́ ló ń dágbére fáyé lọ́dún kan látàrí àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru. 

Ìwádìí ọdún 2023 láti ọwọ Mostafa Hamza, Mollah Naimuzzaman àti Swapan Roy, lórí bóyá  mọ̀ríńgà le wo àìsàn ìtọ̀ súgà fì ìdí rẹ̀ mú lẹ̀ pé ewé mọ̀ríngà ní àwọn èròjà bí “flavonoids àti polyphenols” tó le mú àdínkù débá súgà àti àpọ̀ju isulínì lára. Bákannáà ló le mú kí ìnira dínkù lára látàrí àìsàn ìtọ̀ súgà. 

Ìwádìí ọ̀hún tèsíwájú pé ewé mọ̀ríńgà le fọ ọ̀rá kúrò nínú àgọ́ ara. Ó tún le dènà ara wíwú tó jẹ́ ara ǹkan tó le wáyé nígbà tí ènìyàn bá ní àìsàn ìtọ̀ súgà. Àmọ́, ìwádìí ọ̀hún kò fì dánilójú pé lílo ewé mọ̀ríńgà le wo àìsàn ìtọ̀ súgà pátá pátá. Kódà, ó tẹnumọ́ pé ìwádìí gbọdọ̀ tẹ̀síwájú láti mọ̀ òṣùwọ̀n, àti bóyá kò lè ṣe àkóbá fún ara tí a bá ń lòó fún ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ súgà. 

“Nípa lílo ewé mọ̀ríńgà fún ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ súgà, ìwádìí gbọdọ̀ tẹ̀sìwájù láti mọ̀ òdinwọ̀n, eye ìgbà àti bóyá ó le ṣe àkóbá fún àgó ara. Fún ìdí èyí, lílo ewé mọ̀ríńgà fún àmójútó àìsàn ìtọ̀ súgà gbọdọ̀ wáyé lábẹ́ ìṣàkóso akọ́sẹ́mọsẹ́ oníṣègùn òyìnbó,” àbájáde ìwádìí yìí wí.

Nínú ìwádìí òmíràn tó tọwọ́ Lassana Sissoko, Nouhoun Diarra, Ibrahim Nientao àti Beth Stuart wá lósùn Kọkànlá, Ọ̀dun 2020 lórí lìlo ewé yìí fún ìtọ́jú àìsàn ìtọ̀ súgà, àwọn aṣèwádìí pín àwọn ènìyàn àdọ́rin sì igun méjì (èèyàn márùndínlógójì sí igun kọ̀ọ̀kan), àwọn tó ní àìsàn ìtọ̀ súgà sí apá kan àti àwọn èèyàn tí kò ní àìsàn ọ̀hún sí apá kejì. 

Lẹ́yìn àádọ́rún ìṣẹ́jú tí  àwọn tó ní àìsàn yíì lo gírámú méjì ewé mọ̀ríngà tí wọ́n gún lúbúlúbú, súgà (glucose) tó wà lára wọn dínkù pẹ̀lú ǹǹkan bí 1mmol/l.

Ewé yìí kò sì ní lórí gúlúkósì ara àwọn ènìyàn tí kò ní àìsàn ìtọ̀ súgà.

Ìwádìí ọ̀hún tèsìwájù pé gbogbo àwọn ẹni tó lo mọ̀ríńgà lúbúlúbú ọ̀hún ni kò ṣe àkóbá fún, “àmọ́ ìwádìí mìíràn gbọdọ̀ wáyé láti mọ̀ òdinwọ̀n tó tọ́ fún ìtọ́jú àìsàn ìtọ̀ súgà àti bóyá ó le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.”

Líló èwe Mọ̀ríngà fún ẹ̀jẹ̀ ríru

Àbọ̀ ìwádìí Sailesh Goothy, Andhra Pradesh, àti Jabir P.K lọ́dún 2024, lórí lílo ewé mọ̀ríngà fún ìtọ́jú àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru ṣàlàyé pé omi ewé ọ̀hún lè mú àdínkù débá ẹ̀jẹ̀ ríru. 

Àwọn olùwádìí mú ogún ọkùnrin tó ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru tí ọjọ́ orí wọn wà láàrín ọdún márùndínlógójì sì àádọ́ta. Wọ́n fún wọn ní ewé mọ̀ríngà márúndínlógún lẹ́nìkọ̀’kan, nígbà méjì lójúmọ́, fún ọgbọ́n ọjọ́. 

Àbọ̀ ìwádìí ọ̀hún wípé ẹ̀jẹ̀ ríru wọn dín kù nítorí èròjà bíi “nitrile àti mustard oil.”

Àbájáde íwádìí náà tèsíwájú pé “ewé mọ̀ríńgà le sisẹ́ fún àmójútó àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru. Àmọ́ ìwádìí gbọdọ̀ tèsíwájú láti fì dí rẹ̀ mú lè pé ewé mọ̀ríńgà le wo àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru.”

Bákannáà, nínú íwádìí òmìíràn tí Balaji Subrahmonyan, Lakshmy Senan àti Rabinarayan Tripathy gbé jáde nínú oṣù kọkànlá, ọdún 2021, àwọn olùwádìí kó ènìyàn mẹ́wàá láàárín ogójì ọdún sì ọgọ́rin ọdún tó ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru pẹ̀lú ìfúnpá gíga jọ. Wọ́n sì fún wọn ní ogún gírámù àgbo ewé mọ̀ríngà tí wọ́n sè nínú omi lítà kan. 

Àdínkù tó nítunmọ̀ ló dé bá ìfúnpá wọn lẹyìn ọ̀sẹ̀ madan márùn-ún, “ti kò sì ṣe àkóbá fún àgọ́ ara won”. 

Bákannáà, àwọn olùwádìí yìí wípé “ ìwádìí gbọdo tèsíwájú láti mọ̀ bóyá ewé  mọ̀ríńgà le wo àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru àti òdinwọ̀n tí wón le lò.”

Oyè àwọn onímọ̀ ìṣègun 

DUBAWA kàn sí Moses Adéyeyè, apògùnòyìnbó tó tún jẹ́ adarí ilé-iṣẹ́ Tearyard Pharmaceuticals Stores, Ìwó, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó ṣàlàyé pé lótìítọ́ ní àwọn ewé kan wà bíi ewé mọ̀ríńgà, tó le ṣe àmójútó àìsàn ìtọ̀ súgà àti ẹ̀jẹ̀ ríru. Sùgbọ́n kò sí àrídájú pé wọ́n  le wo àwọn àìsàn náà pátá pátá.

Ó wípé, “Lóòótọ́ ni ewé mọ̀ríngà ṣeé mójú tó àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru

Ó le mú àdínkù débá níní àwọn àìsàn yìí àmọ́ kò sí àrídájú pé ó le wo àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru.”

Arákùnrin Adéyeyè tẹ̀síwájú pé tí àwọn ènìyàn ọ̀hún bá jáwọ́ láti lo ewé mọ̀ríngà fún àmójútó àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, àìsàn ọ̀hún yóò padà. 

DUBAWA tún kàn sí Dókítà Olúfẹ́mi Ayílárá tilé ìwòsàn olùkọ́ni Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Ilé-Ifè, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó ṣàlàyé pé àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú pé ewé mọ̀ríńgà le wo àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru. 

Ó tẹ̀síwájú pé “àwọn ènìyàn kan gbàgbọ́ pé ewé mọ̀ríńgà le fọ ìdọ̀tí ara àmọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú irú ọ̀rọ̀ yìí.

“Ẹnikẹ́ni tó bá ní àìsàn ìtọ̀ súgà tàbí àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru gbọ́dọ̀ lo àwọn àkànṣe ògùn rẹ̀ déédé, kó sì tẹ̀lé ìlànà àwọn oníṣègùn òyìnbó”. 

Bákannáà, Dókítà Adéolú Olúsódo, adarí ilé ìwòsàn Atáyésẹ Òdogbolú, Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣàlàyé pé kò sí àrídájú ìwádìí láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó pé ewé mọ̀ríńgà le wo àìsàn ìtọ̀ súgà àti àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru. Ó rọ̀ àwọn aláìsàn náà lati “má dágunlá, kí wọ́n sì máa ló àwọn ògùn wọn déédé.”

Àkótán

Lótìítọ́, ewé mọ̀ríngà ní àwọn èròjà tó lè ṣe ṣàmójútó àìsàn ìtọ̀ súgà àti ẹ̀jẹ̀ ríru. Sùgbọ́n, àwọn onímọ̀ ìṣègun òyìnbó kò ì tí rí àrídájú pé ó le wo àìsàn wọ̀nyí pátá pátá.

Olùwádìí yìí ṣe ìfìdíòdodo yìí múlẹ̀ lábẹ́ Ìdàpọ̀ Kwame KariKari ti DUBAWA, ọdún 2024, pẹ́lú àjọṣepọ̀ Diamond 88.5FM Nàìjíríà, láti jẹ́ kí òtítọ́ múlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn àti láti fún òtítọ lágbára lórílẹ̀-èdè.


Related Posts