Àhẹ̀sọ: Aṣàmúlò X pín fọ́ran kan tó kéde ìfẹ̀hónúhàn sí Tinúbú lori ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Ábájáde: Ìwádìí fihàn pé fọ́nrán ọ̀hún tí wà níta láti oṣù kejì, ọdún 2024. Àhèsọ náà ṣini lọnà.
Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Ìgbésẹ̀ Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú láti yọ owó ìrànwọ́ epo petiró nínú oṣù karùn-ún ọdún 2023, kété lẹ́yìn ìbúra gẹ́gẹ́bí ààre tí fa ọ̀wọ́n gógó ọjà àti óúnjẹ. Ìpèníjà ọ̀rọ̀ ajẹ̀ tó dojú kọ Nàìjíríà ní àkókò yìí ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnìra fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè, tí púpọ̀ kò sì faramọ́ ìlànà ìṣèjọba Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú.
Ní ọjọ́ kejìlà, oṣù karùn-ún, ọdún 2024, Olóyè T. D Esq, aṣàmúlò X pín fónrán kan tó kéde pé ìfèhónúhàn láti mú kí Tinúbú kúrò lórí ipò ti bẹ̀rẹ̀ ní ẹkùn ìwọ̀oorùn gúsù Nàìjíríà.
Nínú fọ́nrán ọ̀hún ni a rí àwọn olùfẹ̀hónúhàn tó gbé oríṣiríṣi pátákó dání pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bíi “fòpin sí ìnìra Nàìjíríà,” “Tinúbú máa lọ,” “Tinúbú rántí ìbò wa.”
Bí àwọn kan ṣe ń wípé “òti sú wa,” bẹ́ẹ̀ láwọn òmíràn ń pariwo pé “ebi ń pa wá.”
Orísirísi awuyewuye ló ti jẹyọ bí àwọn aṣàmúlò X ṣe ń fèsì sí fọ́nrán ọ̀hún. Iyayi Moses sọ pè gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ dìde láti kọ’jú ìjà sí àwọn aninilára.
“Gbogbo ẹ̀ka yío dìde láti ṣe ìfèhónúhàn. Tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà yío tújáde láti ṣe ìfèhónúhàn tó lágbára, tí wọ́n sì gba orílẹ̀-èdè padà lọ́wọ́ àwon aninilára,” arákùnrin Moses kọ kalẹ̀.
Aṣàmúlò míràn, @FRDKLR14 tí kò gbà ọ̀rọ̀ náà gbọ́ béèrè pé ọjọ́ wo ló ṣẹlẹ̀.
O wípé, “Ṣé ọ̀ní ni?”
Yàtọ̀ sí àwọn méjèèjì, ẹlòmíràn @emifrance1 sọ pé fọ́nrán àtijó ni wọ́n pín.
Ní ṣókí, ó kọ kalẹ̀ pé, “Fọ́nrán àtijọ́ ni.”
Ẹgbẹ̀rún lọ́nà mókànlá ènìyàn ló ti wo fọ́ran yìí, tí ọgọ́rin sì ti pin. DUBAWA pinu láti ṣe ìwádìí yìí nítorí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe gbẹgẹ́ tó.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
DUBAWA lo Google Reverse Image láti ṣe ìwádìí àwọn àwòrán inú fónrán ọ̀hún. Àbájáde sì fìdí rẹ̀ múlè pé fọ́nrán ọ̀hún ti wà lójú òpó You Tube láti ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kejì, ọdún 2024, nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìfèhónúhàn n’ilu Ìbàdàn látàrí ipò ọ̀rọ̀ ajẹ̀ àti ebi ní Nàìjíríà.
Bákannáà, àwọn ilé ìṣe ìròyìn bíi Channels, Leadership, Punch, àti New Telegraph gbé ìròyìn yìí ni ọjọ kọkàndínlógún, oṣù kejì, ọdún 2024 pé àwọn ọ̀dọ ṣe ìfèhónúhàn n’ilu Ìbàdàn látàrí ipò ọ̀rọ̀ ajẹ̀ àti ebi. Láfikún, wọ́n lo irú àwọn àwòrán tó farahàn nínú fọ́nrán yìí.
Àkótán
Ìwádìí fihàn pé fọ́nrán tó kéde ìfẹ̀hónúhàn sí Àrẹ Tinubu láìpẹ́ yìí kìí ṣe titun. Ó ti wà lórí òpó YouTube láti oṣù kejì, ọdún 2024. Àhèsọ náà ṣini lọnà.
The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to facilitate the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.