By Táíwò Adẹ́yemí
Àhẹ̀sọ: Ẹnìkan tó dá sí ètò rédìò kan ṣọ pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikọ́-ife.
Ábájáde: Ìwádìí láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó fì dí rẹ̀ mú lẹ̀ pé kò sí àrídájú pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife.
Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Ẹnìkan tó dá sí ẹ̀tò rédìò kan “Ìlèèra Lọrọ̀” lórí Diamond 88.5FM, Iléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ṣọ pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife. Ó tèsíwájú pé kí ẹni tí àrùn ikọ́-ife yọ lẹ́nu pa akọ aláǹgbá kó din, kó sì jẹ́, àrùn ikọ́-ife yóò sàn.
Àwọn ènìyàn tó lé ní mílíọ́nù mẹ́ta ló ń tẹ́tísí ètò yìí nìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tí àwọn tí wọ́n lé ní mílíọ́nù mẹ́fà sì ń gbọ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ tó sún mọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Gẹ́gẹ́bí àjọ elétò ìlẹ̀ẹ̀ra lágbààyé, WHO, ṣe wí, àrùn ikọ́-ife ló pa àwọn èèyàn tó tó 1.3 million lọ́dún 2022.
WHO tèsíwájú pé àrùn ikó-ife ṣe é wò, tó sì le sàn. Àrùn ọ̀hún ni àwọn èèyàn lùgbàdì nígbà tí wọ́n bá ṣe alábápàdé itó tàbí atẹ́gùn tó wá láti ọ̀dọ àwọn èèyàn tí wón ní àrùn ikó-ife.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Ìwádìí àwọn oníṣègùn òyìnbó fì’dí rẹ̀ mú lẹ̀ pé àwọn ògùn tó le pa kòkòrò aìfojúrí (antibacteria) ni àwọn oníṣègùn òyìnbó lò látí ṣe ìtọ́jú àrùn ikó-ife.
Wọ́n sàlàyé pé lílo ògùn ọ̀hún fún ǹǹkan bí oṣù mẹ́fà nìkan ni àrùn ikó-ife tó le sàn.
DUBAWA kàn sí Dókítà Akíntúndé Ibrahim, ẹ̀ka ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn olùkóni Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Ilé-Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.
Ó wípé “àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife, gbogbo èèyàn tó bá ní ikó-ife kó tètè gba ilé ìwòsàn lọ fún ìtọ́jú tó péye kí àrùn ọ́hún tó pọ̀ lára rẹ̀”.
A tún kàn sí Dókítà Dèjì Gbàdàmósí, ilé ìwòsàn ìjọ́ba Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Asúbíaró, Òsògbo, ẹ̀ka ìtọ́jú àyà àti ikó-ife, tó ti ṣe ìtọ́jú àrùn ikó-ife fún ǹǹkan bí ogún ọdún, lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ṣàlàyé pé irọ́ ni pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikọ́-ife.
Gbàdàmósí tèsíwájú pé “ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife, ẹnikẹ́ni tó bá ní àrùn ọ̀hún, kó tètè lọ ṣe àyẹ̀wò àti ìtọ́jú ní’lé ìwòsàn”.
DUBAWA tún kàn sí Arábìnrin Ọdúnayọ̀ Òní, òṣìṣẹ́ nọ́ọ́sì àti adarí ẹ̀ka ìtọ́jú ikọ́-ife àti ẹ̀tẹ̀ ìjọ́ba ìbílẹ̀ ìlàoorùn Ilésà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, lórí ìbánisọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé kò sí àrídájú pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife.
Òní tèsíwájú pé “kòkòrò aìfojúrí bacteria ló fa ikọ́-ife, tí jíjẹ akọ aláǹgbá kò le wo sàn, ẹnití ó bá ní àrùn ikó-ife kó lọ sí lé ìwòsàn fún ìtọ́jú”.
Àkótán
Àhèsọ pé jíjẹ akọ aláǹgbá le wo àrùn ikó-ife jẹ́ ófégé tó le si àwọn èèyàn lọ́nà.
The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to facilitate the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.