By Táíwò Adéyẹmí
Àhẹ̀sọ: Fọ́nrán kan lójú òpó Facebook ṣàlàyé pé èso atale àti ewé efinrin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí lára.
Àbájáde: Ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn oníṣègùn òyìnbó fihàn pé, kò sí àrídájú pé èso atale àti ewé efinrin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara.
Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́
Wida’du Rosul Islamic Foundation, aṣàmúlò Facebook pín fọ́nrán kàn tí ó wípé èso atale àti ewé efinrin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí (bacteria) lára ènìyàn.
Gẹ́gẹ́bí arákùnrin ọ̀hún ṣe wí, ẹnikẹ́ni tó bá ní àrùn kòkòrò aìfojúrí ni kó mú èso atale kò gé wẹ́wẹ́, kó sì sèé bí àgbo pẹ̀lú ewé efinrin. Ó tèsìwájú pé kí ẹni ọ̀hún ma muú kó tó jẹun láàárọ̀ àti kò tó sùn lálẹ́.
Kòkòrò àifojúrí ni àwọn kòkòrò tí èèyàn kòle fojú lásán rí àmọ́ tí wọ́n ń ṣe àkóbá fún àgọ́ ara.
Àrùn kòkòrò aìfojúrí ara ni àwọn èèyàn lùgbàdì nígbàtí tí wọ́n bá ṣe alábápàdé àwọn èèyàn mìíràn tí wón ní kòkòrò yi lára, afẹ́fẹ́ tó wà láti ọ̀dọ ẹni tó ní àrùn yìí tàbí tí wọ́n bá fi ọwọ́ lé ǹǹkan tí àwọn èèyàn wọ̀nyí ti fọwọ́ kàn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní ló wà nínú èso jínjà bí mímú àdínkù débá ara sísan àti àrùn ìtọ́ ṣúgà.
Bákanáà ni ewé efinrin ń ṣe àgọ́ ara èèyàn ní àǹfààní bí ṣíṣe ìrànwọ́ fún óúnjẹ láti dá àti mímú àdínkù débá ìtọ̀ ṣúgà.
Ìfìdíòdodomúlẹ̀
Ìwádìí láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó fìdí rẹ̀ mú lẹ̀ pé àwọn àkànṣe ògùn ni wọ́n fí ń ṣe ìtọ́jú àrùn kòkòrò àifojúrí ara lẹ́yìn àyẹ̀wò láti mọ èyí tó jẹ́ nínú àwọn àrùn kòkòrò aìfojúrí ara.
DUBAWA kàn sí Dókítà Olúfẹ́mi Ayílárá tilé ìwòsàn olùkọ́ni Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Ilé-Ifè, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó ṣàlàyé pé àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú pé èso jínjà àti ewé efirin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí bakitéríà.
Ó tẹ̀síwájú pé “àwọn èèyàn kan gbàgbọ́ pé èso jínjà le fọ ìdọ̀tí ara àmọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó kòní àrídájú irú ọ̀rọ̀ yìí.”
“Àrùn kòkòrò aìfojúrí ara pé oríṣiríṣi, àhẹ̀sọ pé èso jínjà àti ewé efirin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara jẹ́ ǹǹkan tí kò sí àrídájú rẹ̀.”
Ọ̀gbẹ́ni Ayílárá tẹnumọ́ pé lílo àwọn ǹǹkan bí èso jínjà àti ewé efirin láti tọ́jú àwọn àrùn kòkòrò aìfojúrí ara le se àkóbá fún ágọ́ ara.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ni àgọ́ ara wọ́n ti bàjẹ́ nípa lílo àwọn ńńkan bí èso jínjà àti ewé efirin láti tọ́jú àwọn àrùn bí kòkòrò aìfojúrí ara, kí èèyàn tètè gba ilé ìwòsàn lọ fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú láti borí rẹ̀.”
A tún kàn sí Dókítà Abíọ́dún Ògúnbánjọ ti’lé ìwòsàn God’s First Ìjẹ̀bú-Òde, Ìpínlẹ̀ Ògùn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó ṣàlàyé pé ìwádìí láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú pé èso jínjà àti ewé efirin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara.
Ó tèsíwájú pé “àwọn oníṣègùn òyìnbó kò ní àrídájú pé èso jínjà àti ewé efirin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara. Àwọn èèyàn tí wọ́n ń lo ǹǹkan báyìí ń ṣe àkóbá fún àgọ́ ara wọn.”
“Àrùn kòkòrò aìfojúrí ara pé oríṣiríṣi, èèyàn gbọdọ̀ kọ́kọ́ lọ ṣe àyẹ̀wò kó tó le mọ irú èyíkéyìí tó ń ṣe wọ́n.”
Bákannáà, a tún bá òṣìṣẹ́ nọ́ọ́sì nílé ìwòsàn alábọ́dẹ́ ìjọ̀ba ìbílẹ̀ tì’lú Ìpètu-Ìjẹ̀ṣà, Arábìnrin Oyèyẹmí sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.
Ó ṣàlàyé pé èso jínjà àti ewé efirin kò le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara.
“Lílọ gba ìtọ̀jú nílé ìwòsàn níbití wọ́n ń ti ń ṣe àyẹ̀wò àti ìtọ́jú nìkan lọ̀nà àbáyọ láti wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara sàn”.
Àkótán
Àwọn onímọ̀ ìṣègun kò ì tí rí àrídájú pé èso jínjà àti ewé efinrin le wo àrùn kòkòrò aìfojúrí ara . Ófégé ni ọ̀rọ̀ náà.
The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to enrich the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.