Òtítọ́ ni! Owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ ní Ghana, Benin Republic pọ̀ju ti Nàìjíríà lọ

By Táíwò Adéyẹmí

Àwòrán Àmì Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ NLC àti TUC. Orísun Àwòrán: NLC.

Àhẹ̀sọ: Ẹnìkan tó dá sí ẹ̀tò kan lórí rédíò sọ pé owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ lórílẹ̀-èdè Ghana àti Benin Republic pọ̀ju ti Nàìjíríà lọ. 

Ábájáde: Ìwádìí fì’dí rẹ̀ múlẹ̀ pé, lótìítọ́, owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lọ ní Ghana àti Benin Republic pọ̀ju ti Nàìjíríà lọ.

Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Áwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nigeria Labour Congress (NLC) àti Trade Union Congress (TUC) bẹ̀rẹ̀  ìwosẹ́ nìran lọ́jọ́ ajẹ̀, ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà, ọdún 2024 láti bèèrè fún àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ ní Nàìjíríà.

Ṣáájú nì ìjọba àpapọ̀ ti ṣèlérí láti fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta náírà gẹ́gẹ́bí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlo ní Nàìjíríà, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀ jálẹ̀. 

Ẹnìkan tó dá sí gbajúgbajà ètò rédíò kan lórí Diamond 88.5FM, Iléshà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, sọ pé owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ ní Ghana àti Benin Republic (Cotonou) pọ̀ju ti Nàìjíríà lọ. 

Yàtọ̀ sí ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn olùgbọ́ lójú òpó ayélujára, àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ló gbọ́ ètò yìí, káàkìri ìpínlẹ̀ bíi Èkìtì, Òndó, Kwára, Ọ̀yọ́. Nítorí bí àhesọ yìí ṣe nípọn tó àti àsìkò tó wáyé, DUBAWA pinu láti ṣe ìwádìí yìí.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Ìwádìí fihàn pé owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lọ, tí ìjọba Ghana buwọ́lù lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù  kọkànlá, ọdún 2023 jẹ́ GHS 490,05, èyí tí wọ́n sì tí ń san láti oṣù Kiìíní ọdún 2024. 

Xe.com, ojú òpó  tó ń ṣe  pàsí pàrọ̀ owó fihàn pé GHS 490,05  ni Dollar jẹ́ $33.67 lọ́jọ́ kẹríndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún 2024.

Owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lọ tí’jọba Benin Republic buwọ́lù nínú oṣù kìíní, ọdún 2023 ni FCFA52,000. Afi Xe.com ṣe pàsí-pàrọ̀ owó ọ̀hún sí Dollar, ó sì jẹ́ $85.98 lọ́jọ́ kẹríndínlọ́gbọ̀n, óṣù karùn-ún, Ọdún, 2024.

Ní Nàìjíríà, owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù, tìjọba buwọ́lù nínú oṣù kẹrin ọdún 2019 ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n Náírà (N30,000). Xe.com sì sìró rẹ̀ sí $20.33 lọ́jọ́ kẹríndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún, ọdún 2024.

Àkótán

Pẹ̀lú àbájáde ìwádìí yìí, ó tọ̀nà láti sọ pé òtítọ ni àhesọ náà.

Olùwádìí yìí ṣe ìfìdíòdodo yìí múlẹ̀ lábẹ́ Ìdàpọ̀ Kwame KariKari ti DUBAWA, ọdún 2024, pẹ́lú àjọṣepọ̀ Diamond 88.5FM Nàìjíríà, láti jẹ́ kí òtítọ́ múlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn àti láti fún òtítọ lágbára lórílẹ̀-èdè.

Related Posts