Irọ́! Kò sí òògùn kan pàtó fún àìsàn olóde

By Táíwò Adéyẹmí

Orísun Àwòrán: Dream Time.

Àhẹ̀sọ: Aṣàmúlò TikTok kan wípé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le wo àìsàn olóde (measles).

Ábájáde: Ìwádìí àti ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn oníṣègùn òyìnbó fi hàn pé kò tíì sí ògùn kan pàtó fún àìsàn olóde. Bákannáà, kò sí àrídájú pé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le ṣe ìwòsàn fun.

Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Tí ọmọdé bá ń ṣe òjòjò, kò sí òbí t’ójú rẹ̀ yíó gbà á láti ma wò ó níran. Èyí ló fàá tí àwọn òbí ọlọ́mọ wẹ́wẹ́ fi ma ń gba oríṣiríṣi ọnà láti ṣe ìtọ́jú fún ọmọ tí ara rẹ̀ kò bá yá.

Láìpẹ́ yìí, Hardukeeherbs, aṣàmúlò TikTok pín fọ́nrán kan tó wí pé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le wo àìsàn olóde.

Arábìnrin ọ̀hún rọ àwọn òbí tí ọmọ wọn bá ní àìsàn olóde láti mú ẹfun, kí wọ́n gun lúbúlúbú, kí wọ́n dàá sínú ọtí ìbílẹ̀, kí wọ́n sì fí pa ọmọ náà làra. O wípé àìsàn náà yí ó pòórá.

Àìsàn olóde le fa ara gbígbóná àti kòkòrò sì ara. Ó le ràn kíá kíá tí èèyàn bá ṣe alábápàdé afẹ́fẹ́ tó wá láti ọ̀dọ ẹni tó ní àìsàn yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà àwọn ọmọ kéékèèké ni àìsàn olóde má ń mú, tí àwọn ọmọ yíì kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára. Ara àwọn àmì àìsàn olóde míràn ni ikọ́ àti ojú pípọ́n.

Àwọn èèyàn tí wón tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́jẹ ló dágbére fáyé lọ́dún 2018. Púpọ̀ nínú wọn ló jẹ́ ọmọ kékèèké.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

Ìwádìí fi hàn pé kò sí ògùn kan ní pàtó tó le wo àìsàn olóde, àwọn àmì àìsàn ọ̀hún nìkan ni èèyàn le tọ́jú.

DUBAWA kàn sí Dókítà Adéolú Olúsódo, adarí ilé ìwòsàn Atáyésẹ Òdogbolú, Ìpínlẹ̀ Ògùn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó ṣàlàyé pé kò sí àrídájú pé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le wo àìsàn olóde.

Ó tèsìwájú pé kòkòrò aìfojúrí ló ń fa àìsàn olóde. “Ó léwu láti lo ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun fún ìtọ́jú àìsàn olóde torí irú àwọn ǹǹkan bí ọtí àti ẹfun kò ní òdinwọ̀n láti mọ ìgbà tàbí òṣùwọ̀n iye tó yẹ láti lò”.

A tún kàn sí Dókítà Olúfẹ́mi Ayílárá ti’lé ìwòsàn olùkọ́ni Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ Ilé-Ifè, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni pé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le wo àìsàn olóde.

Ayílárá tẹ̀sìwájú pé “kòkòrò aìfojúrí tí àwọn èèyàn lùgbàdì ló ń fa àìsàn olóde, tí kò sì sí àrídájú láti ọwọ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó pé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le pa àwọn kòkòrò aìfojúrí yìí”.

A bá Adarí ìpòlongo fún ọ̀rọ̀ ìlẹra ìjọ̀ba ìbílẹ̀ ìwọ̀oorùn Ilésà, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tó tún jẹ́ òṣìṣẹ́ nọ́ọ́ṣì, Tolúlọpẹ́ Ọlájùmòkẹ́ sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó ṣàlàyé pé kò sí àrídájú kankan pé ọtí ìbílẹ̀ le wo àìsàn olóde àti wípé gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn ọmọ ìkókó kí wọ́n tó pé ọmọ oṣù méjìlá nìkàn ló lè dènà rẹ̀.

Ó tẹ̀sìwájú pé “àìsàn olóde ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkóbá fún àwọn ọmọ kéékèèké, nígbà míràn ó le fa kí ojú ọmọ fọ́ tàbí kí ọmọ padà kú”.

Àkótán

Àwọn onímọ̀ ìṣègun kò ì tí rí àrídájú pé ọtí ìbílẹ̀ àti ẹfun le wo àìsàn olóde.

The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to enrich the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.

Related Posts