Ǹjẹ́ Gómìnà Adélékè buwọ́lu bíliọnù lọ́nà Ọgbọ́n Náírà fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe ní’lú  Ẹdẹ?

Àhẹ̀sọ: Ọmo ẹgbẹ́ òṣèlú oní’tèsìwájú (APC) làti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, lórí ètò rédìò kan, wípé Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Adémólá Adélèké buwọ́lu N30 bíliọnù fún iṣẹ́ àkànṣe sìlú Ẹdẹ.

Ábájáde: Ìwádìí fì’di rẹ̀ múlè pé Gómìnà Adémólá Adélékè kò buwọ́lu owó fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe mìíràn àyàfi èyí tó wà nínú ètò ìṣúná ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún Ọdún 2024 tíjọba sì ń sisẹ́ lè lórí. Ófégé ni ọ̀rọ̀ náà.

Àlàyé Lẹ́kùńrẹ́rẹ́

Ọmo ẹgbẹ́ òṣèlú òní’tèsìwájú, APC, nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórí ètò rédíò kan “APC Reconciliation Half Hour” fẹ̀sùn kan Gómìnà Adémólá Adélékè tìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun pé ó buwọ́lu N30 bíliọnù nínú N60 bíliọnù tí wọn yà sọ́tọ̀ fún ìdàgbàsókè ohun amáyedèrùn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.Àwọn ènìyàn tí wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ló ma ń tẹ́tísí ètò yìí nìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tí àwọn tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà sì ń gbọ ní àwọn ìpínlẹ̀ tó sún mọ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Ìfìdíòdodomúlẹ̀

DUBAWA kàn sí agbẹnusọ fún Gómìnà Adélékè, Ọláwálé Rasheed lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò bu owó titun fún iṣẹ́ àkànṣe tàbí ọgbọ̀n bíliọnù fún ìlú Ẹdẹ níkan.Arákùnrin Rasheed tèsìwájú pé gbogbo ìlànà ètò owó níná ìjọ̀ba fún ọdún 2024 ló wà nínú ètò ìṣúná ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fún ọdún 2024. Ó wípé: “Ìjọ̀ba Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò bùwọ́lu owó titun fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe titun tàbí fún ‘lú Ẹdẹ bí àwọn ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ṣe wí. Àwọn ìlànà ohun amáyedẹ̀rùn tí Gómínà Adémólá Adélékè fi léde ló wà nínú ètò ìṣúná ọdún 2024, tìjọ́ba Adélékè tẹ̀ lé gẹ́gẹ́bí ilé ìgbìmò asòfin ṣe fọwọ́ ṣí.”

Àkótán

Àhèsọ pé gómìnà Adémólá Adélékè buwọ́lu N30 bíliọnù fún ìlú Ẹdẹ níkan jẹ́ ófégé tó le si àwọn èèyàn lọ́nà.

The researcher produced this fact-check per the DUBAWA 2024 Kwame KariKari Fellowship, in partnership with Diamond 88.5 FM Nigeria, to facilitate the ethos of “truth” in journalism and enhance media literacy in the country.

Related Posts